13 Ọba sọ àwọn ibi gíga tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, èyí tó wà ní gúúsù* Òkè Ìparun,* tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì mọ fún Áṣítórétì abo ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Sídónì; fún Kémóṣì ọlọ́run ìríra Móábù àti fún Mílíkómù+ ọlọ́run ẹ̀gbin àwọn ọmọ Ámónì.+
17 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé ìwọ náà rí i? Ṣé ohun tí kò tó nǹkan ni lójú ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, tí wọ́n ń hu ìwà ipá ní gbogbo ilẹ̀ náà,+ tí wọ́n sì ń ṣẹ̀ mí? Wọ́n ń na ẹ̀ka* sí mi ní imú.