12 Ṣé kí àwọn ará Íjíbítì wá máa sọ pé, ‘Èrò ibi ló wà lọ́kàn rẹ̀ nígbà tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ wa. Ṣe ló fẹ́ pa wọ́n síbi àwọn òkè, kó sì run wọ́n kúrò lórí ilẹ̀’?+ Má ṣe jẹ́ kínú bí ọ sí wọn, jọ̀ọ́ pèrò dà nípa ìpinnu tí o ṣe láti mú àjálù yìí bá àwọn èèyàn rẹ.