-
Ẹ́kísódù 14:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Ó ń mú kí àgbá kẹ̀kẹ́ yọ kúrò lára àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn, ìyẹn sì ń mú kó nira fún wọn láti wa àwọn kẹ̀kẹ́ náà, àwọn ará Íjíbítì sì ń sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká fọwọ́ kan Ísírẹ́lì rárá o, torí Jèhófà ń gbèjà wọn, ó sì ń bá àwa ọmọ Íjíbítì jà.”+
-
-
1 Sámúẹ́lì 4:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 A ti dáràn! Ta ló máa gbà wá lọ́wọ́ Ọlọ́run títóbi yìí? Ọlọ́run yìí ló pa àwọn ará Íjíbítì lóríṣiríṣi ọ̀nà ní aginjù.+
-
-
Ẹ́sírà 1:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tó wà ní Júdà. 3 Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lọ sí Jerúsálẹ́mù tó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́, òun ni Ọlọ́run tòótọ́, tí ilé rẹ̀ wà ní Jerúsálẹ́mù.*
-