-
1 Kọ́ríńtì 10:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe; gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Àwọn èèyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu. Wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.”+ 8 Bákan náà, kí a má ṣe ìṣekúṣe,* bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe ìṣekúṣe,* tí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000) lára wọn fi kú ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+
-