-
Ẹ́kísódù 22:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá rúbọ sí ọlọ́run èyíkéyìí yàtọ̀ sí Jèhófà.+
-
-
Ẹ́kísódù 32:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Mósè rí i pé apá ò ká àwọn èèyàn náà mọ́, torí Áárónì ti fàyè gbà wọ́n, wọ́n sì ti di ẹni ìtìjú lójú àwọn alátakò wọn.
-
-
Ẹ́kísódù 32:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Kí kálukú yín sán idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, kí ẹ sì lọ káàkiri àgọ́ náà láti ẹnubodè sí ẹnubodè, kí kálukú pa arákùnrin rẹ̀, aládùúgbò rẹ̀ àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.’”+
-
-
Diutarónómì 13:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Tí arákùnrin rẹ, ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ tàbí ìyàwó rẹ tí o fẹ́ràn tàbí ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́,* bá gbìyànjú láti tàn ọ́ ní ìkọ̀kọ̀ pé, ‘Jẹ́ ká lọ sin àwọn ọlọ́run míì,’+ àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀, 7 lára àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká, ì báà jẹ́ nítòsí tàbí àwọn tó jìnnà sí yín, láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ náà dé ìpẹ̀kun rẹ̀ kejì, 8 o ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn tàbí kí o fetí sí i,+ o ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀ tàbí kí o yọ́nú sí i, o ò sì gbọ́dọ̀ dáàbò bò ó; 9 kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí o pa á.+ Ọwọ́ rẹ ni kó kọ́kọ́ bà á láti pa á, lẹ́yìn náà, kí gbogbo èèyàn dáwọ́ jọ kí wọ́n lè pa á.+
-