-
Diutarónómì 5:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Nínú gbogbo aráyé,* ta ló tíì gbọ́ ohùn Ọlọ́run alààyè tó ń sọ̀rọ̀ látinú iná bí a ṣe gbọ́ ọ, tí onítọ̀hún ò sì kú?
-
-
2 Sámúẹ́lì 7:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Orílẹ̀-èdè wo ní gbogbo ayé ló dà bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì?+ Ọlọ́run lọ rà wọ́n pa dà nítorí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀,+ ó sì ṣe orúkọ fún ara rẹ̀+ bí ó ṣe ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àgbàyanu fún wọn.+ O lé àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọlọ́run wọn jáde nítorí àwọn èèyàn rẹ, tí o rà pa dà fún ara rẹ láti Íjíbítì.
-