-
Nọ́ńbà 21:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Àmọ́ Síhónì ò jẹ́ kí Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Síhónì kó gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, wọ́n sì lọ gbéjà ko Ísírẹ́lì ní aginjù, nígbà tí wọ́n dé Jáhásì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá Ísírẹ́lì+ jà. 24 Àmọ́ Ísírẹ́lì fi idà+ ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì gba ilẹ̀+ rẹ̀ láti Áánónì+ lọ dé Jábókù,+ nítòsí àwọn ọmọ Ámónì, torí pé ààlà àwọn ọmọ Ámónì+ ni Jásérì+ wà.
-
-
Jóṣúà 12:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Àwọn ọba ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun nìyí, tí wọ́n gba ilẹ̀ wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, láti Àfonífojì Áánónì+ dé Òkè Hámónì+ àti gbogbo Árábà lápá ìlà oòrùn:+ 2 Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì, tó sì ń jọba láti Áróérì,+ tó wà létí Àfonífojì Áánónì+ àti láti àárín àfonífojì náà àti ìdajì Gílíádì títí dé Àfonífojì Jábókù, ààlà àwọn ọmọ Ámónì.
-