-
Nehemáyà 9:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 O wá ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu láti fìyà jẹ Fáráò àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ rẹ̀,+ torí o mọ̀ pé wọ́n ti kọjá àyè wọn+ sí àwọn èèyàn rẹ. O ṣe orúkọ fún ara rẹ, orúkọ náà sì wà títí dòní.+ 11 O pín òkun sí méjì níwájú wọn, kí wọ́n lè gba àárín òkun kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ,+ o fi àwọn tó ń lépa wọn sọ̀kò sínú ibú bí òkúta tí a jù sínú omi tó ń ru gùdù.+
-
-
Jeremáyà 32:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 O ti ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Íjíbítì, tí a mọ̀ títí di òní yìí, o sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe orúkọ fún ara rẹ ní Ísírẹ́lì àti láàárín aráyé+ bó ṣe rí lónìí yìí.
-