ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 7:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ní tèmi, màá jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ màá sì ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+

  • Ẹ́kísódù 7:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ó sì dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nígbà tí mo bá na ọwọ́ mi láti bá Íjíbítì jà, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò láàárín wọn.”

  • Ẹ́kísódù 9:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Mi ò bá ti na ọwọ́ mi kí n lè fi àjàkálẹ̀ àrùn tó le gan-an kọ lu ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ, kí n sì pa ọ́ rẹ́* kúrò ní ayé. 16 Àmọ́ ìdí tí mo fi dá ẹ̀mí rẹ sí ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a sì lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.+

  • Diutarónómì 4:34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Àbí Ọlọ́run ti gbìyànjú láti mú orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ látinú orílẹ̀-èdè míì pẹ̀lú àwọn ìdájọ́,* àmì, iṣẹ́ ìyanu,+ ogun,+ pẹ̀lú ọwọ́ agbára,+ apá tó nà jáde, tó sì ṣe àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe fún yín ní Íjíbítì níṣojú yín?

  • 2 Sámúẹ́lì 7:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Orílẹ̀-èdè wo ní gbogbo ayé ló dà bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì?+ Ọlọ́run lọ rà wọ́n pa dà nítorí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀,+ ó sì ṣe orúkọ fún ara rẹ̀+ bí ó ṣe ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àgbàyanu fún wọn.+ O lé àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọlọ́run wọn jáde nítorí àwọn èèyàn rẹ, tí o rà pa dà fún ara rẹ láti Íjíbítì.

  • Àìsáyà 63:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ẹni tó mú kí apá Rẹ̀ ológo bá ọwọ́ ọ̀tún Mósè lọ,+

      Ẹni tó pín omi níyà níwájú wọn,+

      Kó lè ṣe orúkọ tó máa wà títí láé fún ara rẹ̀,+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́