25 Ẹnì kankan ò ní dìde sí yín.+ Jèhófà Ọlọ́run yín máa kó jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn gbogbo ilẹ̀ tí ẹ máa tẹ̀, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù yín,+ bó ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.
5 Kò sẹ́ni tó máa lè dìde sí ọ ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè.+ Bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mósè ni màá ṣe wà pẹ̀lú rẹ.+ Mi ò ní pa ọ́ tì, mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.+