-
Nọ́ńbà 13:23-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Nígbà tí wọ́n dé Àfonífojì Éṣíkólì,+ wọ́n gé ẹ̀ka àjàrà tó ní òṣùṣù èso àjàrà kan, méjì lára àwọn ọkùnrin náà sì fi ọ̀pá gbọọrọ kan gbé e, pẹ̀lú pómégíránétì díẹ̀ àti èso ọ̀pọ̀tọ́+ díẹ̀. 24 Wọ́n pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Éṣíkólì,*+ torí òṣùṣù èso tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gé níbẹ̀.
25 Lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́,+ wọ́n pa dà láti ilẹ̀ tí wọ́n ti lọ ṣe amí. 26 Wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Páránì, ní Kádéṣì.+ Wọ́n jábọ̀ fún gbogbo àpéjọ náà, wọ́n sì fi àwọn èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Ohun tí wọ́n ròyìn fún Mósè ni pé: “A dé ilẹ̀ tí o rán wa lọ, wàrà àti oyin+ sì ń ṣàn níbẹ̀ lóòótọ́, àwọn èso+ ibẹ̀ nìyí.
-