7 Ẹni ogójì (40) ọdún ni mí nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà rán mi láti Kadeṣi-báníà lọ ṣe amí ilẹ̀ náà,+ bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ ni mo sọ ọ́ nígbà tí mo dé.+ 8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin mi tí a jọ lọ mú kí ọkàn àwọn èèyàn wa domi, mo fi gbogbo ọkàn mi tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run mi.+