-
Diutarónómì 12:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Kàkà bẹ́ẹ̀, ibikíbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ wà àti ibi tó bá ń gbé láàárín gbogbo ẹ̀yà yín ni kí ẹ ti máa wá a, ibẹ̀ sì ni kí ẹ máa lọ.+
-
-
Diutarónómì 15:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 “Gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti nínú agbo ẹran rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ fi àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran* rẹ ṣe iṣẹ́ kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ rẹ́ irun àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ. 20 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ àti agbo ilé rẹ ti máa jẹ ẹ́ lọ́dọọdún ní ibi tí Jèhófà máa yàn.+
-