-
Diutarónómì 12:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Kàkà bẹ́ẹ̀, ibikíbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ wà àti ibi tó bá ń gbé láàárín gbogbo ẹ̀yà yín ni kí ẹ ti máa wá a, ibẹ̀ sì ni kí ẹ máa lọ.+ 6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú àwọn ẹbọ sísun yín wá+ àti àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín àti àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín.+ 7 Ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin àti àwọn agbo ilé yín ti jẹun níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì máa yọ̀ nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ti bù kún yín.
-