14 “Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí ẹ máa ṣe àjọyọ̀ fún mi.+ 15 Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.+ Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú ní àkókò rẹ̀ nínú oṣù Ábíbù,+ bí mo ṣe pa á láṣẹ fún yín, torí ìgbà yẹn lẹ kúrò ní Íjíbítì. Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wá síwájú mi lọ́wọ́ òfo.+