11 Ógù ọba Báṣánì ló ṣẹ́ kù nínú àwọn Réfáímù. Irin* ni wọ́n fi ṣe àga ìgbókùú* rẹ̀, ó ṣì wà ní Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* mẹ́sàn-án, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, wọ́n lo ìgbọ̀nwọ́ tó péye.
6 Ogun tún wáyé ní Gátì,+ níbi tí ọkùnrin kan wà tí ó tóbi fàkìàfakia,+ ó ní ìka mẹ́fà-mẹ́fà ní ọwọ́ àti ní ẹsẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlélógún (24); òun náà sì wà lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+