-
2 Sámúẹ́lì 21:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ogun tún wáyé ní Gátì, níbi tí ọkùnrin kan wà tí ó tóbi fàkìàfakia, ó ní ìka mẹ́fà-mẹ́fà ní ọwọ́ àti ní ẹsẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlélógún (24); òun náà sì wà lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+ 21 Ó ń pẹ̀gàn Ísírẹ́lì.+ Torí náà, Jónátánì ọmọ Ṣíméì,+ ẹ̀gbọ́n Dáfídì, pa á.
22 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí jẹ́ àtọmọdọ́mọ Réfáímù ní Gátì, Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló sì pa wọ́n.+
-