23 Ó tún mú ọkùnrin ará Íjíbítì kan tó tóbi fàkìàfakia balẹ̀ tó ga ní ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.+ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kọ̀ tó wà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ,+ ó fi ọ̀pá bá a jà, ó já ọ̀kọ̀ náà gbà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ òun fúnra rẹ̀ pa á.+