-
1 Kíróníkà 20:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ogun tún wáyé ní Gátì,+ níbi tí ọkùnrin kan wà tí ó tóbi fàkìàfakia,+ ó ní ìka mẹ́fà-mẹ́fà ní ọwọ́ àti ní ẹsẹ̀, gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlélógún (24); òun náà sì wà lára àwọn àtọmọdọ́mọ Réfáímù.+ 7 Ó ń pẹ̀gàn+ Ísírẹ́lì. Torí náà, Jónátánì ọmọ Ṣíméà,+ ẹ̀gbọ́n Dáfídì, pa á.
8 Àwọn yìí jẹ́ àtọmọdọ́mọ Réfáímù+ ní Gátì,+ Dáfídì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló sì pa wọ́n.
-