-
Ẹ́kísódù 17:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé fún ìrántí, kí o sì tún un sọ fún Jóṣúà pé, ‘Màá mú kí wọ́n gbàgbé Ámálékì pátápátá lábẹ́ ọ̀run.’”+
-
-
1 Sámúẹ́lì 14:47, 48Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
47 Sọ́ọ̀lù fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì, ó sì bá gbogbo ọ̀tá rẹ̀ jà níbi gbogbo, ó bá àwọn ọmọ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ jà, ó tún bá àwọn ọmọ Édómù+ àti àwọn ọba Sóbà+ pẹ̀lú àwọn Filísínì+ jà; ó sì ń ṣẹ́gun níbikíbi tó bá lọ. 48 Ó fi ìgboyà jà, ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì,+ ó sì gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn tó ń kó ohun ìní wọn lọ.
-
-
1 Sámúẹ́lì 15:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nígbà náà, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Jèhófà rán mi láti fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ní báyìí, gbọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ sọ.+ 2 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: ‘Màá pe àwọn ọmọ Ámálékì wá jíhìn nítorí ohun tí wọ́n ṣe sí Ísírẹ́lì bí wọ́n ṣe gbéjà kò ó nígbà tó ń jáde bọ̀ láti Íjíbítì.+ 3 Ní báyìí, lọ ṣá àwọn ọmọ Ámálékì+ balẹ̀, kí o sì pa wọ́n run pátápátá+ pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní. O ò gbọ́dọ̀ dá wọn sí;* ṣe ni kí o pa gbogbo wọn,+ ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti ọmọ jòjòló, akọ màlúù àti àgùntàn, ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’”+
-