14 Ó kó gbogbo Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn, gbogbo ìjòyè,+ gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú gbogbo oníṣẹ́ irin,*+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kó lọ sí ìgbèkùn. Kò ṣẹ́ ku ẹnì kankan àfi àwọn aláìní ní ilẹ̀ náà.+
15 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ sì kó àwọn kan lára àwọn aláìní nínú àwọn èèyàn náà àti àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìlú náà lọ sí ìgbèkùn. Ó tún kó àwọn tó sá lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì àti ìyókù àwọn àgbà oníṣẹ́ ọnà lọ sí ìgbèkùn.+
30 Ní ọdún kẹtàlélógún Nebukadinésárì,* Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn Júù lọ sí ìgbèkùn, àwọn èèyàn* náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé márùndínláàádọ́ta (745).+
Lápapọ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (4,600) èèyàn* ni wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn.