-
Diutarónómì 11:26-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 “Wò ó, mò ń fi ìbùkún àti ègún síwájú yín lónìí:+ 27 ẹ máa rí ìbùkún tí ẹ bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí mò ń pa fún yín lónìí,+ 28 àmọ́ ègún máa wà lórí yín bí ẹ kò bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ tí ẹ sì yà kúrò lójú ọ̀nà tí mò ń pa láṣẹ fún yín pé kí ẹ máa rìn lónìí, tí ẹ wá lọ ń tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run tí ẹ ò mọ̀.
-