ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 28:45
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 45 “Ó dájú pé gbogbo ègún+ yìí máa wá sórí rẹ, ó máa tẹ̀ lé ọ, ó sì máa bá ọ, títí o fi máa pa run,+ torí pé o ò tẹ̀ lé àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó pa láṣẹ+ fún ọ, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀.

  • Diutarónómì 28:63
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 63 “Bí inú Jèhófà ṣe dùn nígbà kan láti mú kí nǹkan máa lọ dáadáa fún yín, kí ẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni inú Jèhófà ṣe máa dùn láti pa yín run kó sì pa yín rẹ́; ẹ sì máa pa run kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà.

  • 1 Àwọn Ọba 14:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Jèhófà yóò kọ lu Ísírẹ́lì, á sì dà bí esùsú* tó ń mì lòólòó lójú omi, yóò fa Ísírẹ́lì tu kúrò lórí ilẹ̀ dáradára yìí tó fún àwọn baba ńlá wọn,+ yóò sì tú wọn ká kọjá Odò,*+ nítorí wọ́n ṣe àwọn òpó òrìṣà,*+ tí wọ́n sì ń mú Jèhófà bínú.

  • 2 Àwọn Ọba 17:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Nítorí náà, inú bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì, tí ó fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀.+ Kò jẹ́ kí èyíkéyìí ṣẹ́ kù lára wọn àfi ẹ̀yà Júdà nìkan.

  • Lúùkù 21:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Wọ́n máa fi ojú idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n á sì kó wọn lẹ́rú lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè;+ àwọn orílẹ̀-èdè* sì máa tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè* fi máa pé.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́