7 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọba ilẹ̀ tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì, láti Baali-gádì,+ ní Àfonífojì Lẹ́bánónì+ títí dé Òkè Hálákì,+ tó lọ dé Séírì,+ tí Jóṣúà wá fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ àwọn ọba náà pé kó di tiwọn, bí ìpín wọn,+