-
Nọ́ńbà 21:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Àmọ́ Síhónì ò jẹ́ kí Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Síhónì kó gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, wọ́n sì lọ gbéjà ko Ísírẹ́lì ní aginjù, nígbà tí wọ́n dé Jáhásì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá Ísírẹ́lì+ jà. 24 Àmọ́ Ísírẹ́lì fi idà+ ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì gba ilẹ̀+ rẹ̀ láti Áánónì+ lọ dé Jábókù,+ nítòsí àwọn ọmọ Ámónì, torí pé ààlà àwọn ọmọ Ámónì+ ni Jásérì+ wà.
-
-
Nọ́ńbà 21:33-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà, wọ́n sì lọ gba Ọ̀nà Báṣánì. Ógù+ ọba Báṣánì àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ sì jáde wá gbéjà kò wọ́n ní Édíréì.+ 34 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Má bẹ̀rù rẹ̀,+ torí màá fi òun àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́,+ ohun tí o ṣe sí Síhónì, ọba àwọn Ámórì tó gbé ní Hẹ́ṣíbónì+ gẹ́lẹ́ ni wàá ṣe sí i.” 35 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jà, títí ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ ò fi ṣẹ́ kù,+ wọ́n sì gba ilẹ̀+ rẹ̀.
-