-
Nọ́ńbà 18:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Torí mo ti fi ìdá mẹ́wàá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa mú wá fún Jèhófà ṣe ogún fún àwọn ọmọ Léfì. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún wọn pé, ‘Wọn ò gbọ́dọ̀ ní ogún+ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”
-
-
Nọ́ńbà 26:62, 63Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
62 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000), gbogbo wọn jẹ́ ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè.+ Wọn ò forúkọ wọn sílẹ̀ pẹ̀lú ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ torí wọn ò fún wọn ní ogún kankan láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
63 Èyí ni àwọn tí Mósè àti àlùfáà Élíásárì forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, nítòsí Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò.
-
-
Diutarónómì 18:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “Wọn ò ní fún àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì àti gbogbo ẹ̀yà Léfì pátá ní ìpín tàbí ogún kankan ní Ísírẹ́lì. Wọ́n á máa jẹ lára àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, èyí tó jẹ́ tirẹ̀.+
-