16 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n bá wọn dá májẹ̀mú, wọ́n gbọ́ pé tòsí wọn ni wọ́n ń gbé, ọ̀nà wọn ò sì jìn rárá. 17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá gbéra, wọ́n sì dé àwọn ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta; àwọn ìlú wọn ni Gíbíónì,+ Kéfírà, Béérótì àti Kiriati-jéárímù.+
2 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá lọ sí Baale-júdà kí wọ́n lè gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́+ wá láti ibẹ̀, iwájú rẹ̀ ni àwọn èèyàn ti ń ké pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù.+
6 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì lọ sí Báálà,+ sí Kiriati-jéárímù ti Júdà, kí wọ́n lè gbé Àpótí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ wá láti ibẹ̀, ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù,+ ibi tí a ti ń ké pe orúkọ rẹ̀.