13 gbàrà tí àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí Jèhófà, Olúwa gbogbo ayé bá kan* omi Jọ́dánì, omi Jọ́dánì tó ń ṣàn wá látòkè máa dáwọ́ dúró, ó sì máa dúró bí ìsédò.”*+
15 Gbàrà tí àwọn tó gbé Àpótí náà dé Jọ́dánì, tí àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí náà sì ki ẹsẹ̀ wọn bọ etí omi náà (ó ṣẹlẹ̀ pé odò Jọ́dánì máa ń kún bo bèbè rẹ̀+ ní gbogbo ọjọ́ ìkórè),