2 Àwọn ọmọ Dánì rán ọkùnrin márùn-ún látinú ìdílé wọn, àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti Sórà àti Éṣítáólì+ pé kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.” Nígbà tí wọ́n dé agbègbè olókè Éfúrémù, ní ilé Míkà,+ wọ́n sun ibẹ̀ mọ́jú.