18 Nígbà náà, Júdà gba Gásà+ àti agbègbè rẹ̀, Áṣíkẹ́lónì+ àti agbègbè rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ́kírónì+ àti agbègbè rẹ̀. 19 Jèhófà wà pẹ̀lú Júdà, wọ́n sì gba agbègbè olókè náà, àmọ́ wọn ò lè lé àwọn tó ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà kúrò, torí pé wọ́n ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin.+