4 Ni wọ́n bá béèrè pé: “Ọrẹ ẹ̀bi wo ni ká fi ránṣẹ́ sí i?” Wọ́n sọ pé: “Ẹ fi jẹ̀díjẹ̀dí* wúrà márùn-ún àti eku wúrà márùn-ún ránṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn alákòóso Filísínì,+ nítorí irú àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọ lu ẹnì kọ̀ọ̀kan yín àti àwọn alákòóso yín.
17 Àwọn jẹ̀díjẹ̀dí wúrà tí àwọn Filísínì fi ránṣẹ́ láti fi ṣe ọrẹ ẹ̀bi fún Jèhófà nìyí:+ ọ̀kan fún Áṣídódì,+ ọ̀kan fún Gásà, ọ̀kan fún Áṣíkẹ́lónì, ọ̀kan fún Gátì,+ ọ̀kan fún Ẹ́kírónì.+