10Ìgbà náà ni Sámúẹ́lì mú ṣágo* òróró, ó sì da òróró inú rẹ̀ sórí Sọ́ọ̀lù.+ Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ Jèhófà kò ti fòróró yàn ọ́ ṣe aṣáájú+ lórí ogún rẹ̀?+
15Nígbà náà, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Jèhófà rán mi láti fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ní báyìí, gbọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ sọ.+