ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 17:9, 10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ọlọ́run tún sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní tìrẹ, kí o pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn. 10 Májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nìyí, òun sì ni ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò máa pa mọ́: Gbogbo ọkùnrin tó wà láàárín yín gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́.*+

  • Àwọn Onídàájọ́ 14:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Àmọ́, bàbá àti ìyá rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé o ò rí obìnrin kankan láàárín àwọn mòlẹ́bí rẹ àti gbogbo àwọn èèyàn wa ni?+ Ṣé àárín àwọn Filísínì aláìdádọ̀dọ́* ló yẹ kí o ti lọ fẹ́ ìyàwó?” Àmọ́ Sámúsìn sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Òun ni kí o fẹ́ fún mi, torí òun lẹni tó yẹ mí.”*

  • Àwọn Onídàájọ́ 15:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Òùngbẹ wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ ẹ́ gan-an, ló bá ké pe Jèhófà, ó sì sọ pé: “Ìwọ lo jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ ṣẹ́gun lọ́nà tó kàmàmà, àmọ́ ṣé kí òùngbẹ wá pa mí ni, kí ọwọ́ àwọn aláìdádọ̀dọ́* sì tẹ̀ mí?”

  • 1 Sámúẹ́lì 17:36
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 36 Àti kìnnìún àti bíárì náà ni ìránṣẹ́ rẹ pa, Filísínì aláìdádọ̀dọ́* yìí á sì dà bí ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pẹ̀gàn àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè.”*+

  • 1 Kíróníkà 10:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́* yìí má bàa wá hùwà ìkà+ sí mi.”* Àmọ́, ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ẹ̀rù bà á gan-an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lé e.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́