6 Nítorí náà, Jónátánì sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Wá, jẹ́ ká sọdá lọ sọ́dọ̀ àwùjọ ọmọ ogun aláìdádọ̀dọ́+ tó wà ní àdádó yìí. Bóyá Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́, nítorí kò sí ohun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti gbani là, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àwọn tó pọ̀ tàbí àwọn díẹ̀.”+