18 Ni Ábígẹ́lì+ bá sáré mú igba (200) búrẹ́dì àti wáìnì ìṣà ńlá méjì àti àgùntàn márùn-ún tí wọ́n ti pa, tí wọ́n sì ti ṣètò rẹ̀ àti òṣùwọ̀n síà márùn-ún àyangbẹ ọkà àti ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù èso àjàrà gbígbẹ àti igba (200) ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì kó gbogbo wọn sórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+