10 Lọ́jọ́ kejì, Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ̀mí búburú mú Sọ́ọ̀lù,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe wọ́nranwọ̀nran nínú ilé, bí Dáfídì ṣe ń fi háàpù+ kọrin lọ́wọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù,+ 11 ó sì ju ọ̀kọ̀ náà,+ ó sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Màá gún Dáfídì mọ́ ògiri!’ Àmọ́ Dáfídì sá mọ́ ọn lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀mejì.