-
1 Kíróníkà 15:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Dáfídì wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí wọ́n fi aṣọ àtàtà ṣe, bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó gbé Àpótí náà ṣe múra, àwọn akọrin àti Kenanáyà olórí tó ń bójú tó gbígbé ẹ̀rù àti àwọn tó ń kọrin; Dáfídì sì tún wọ éfódì+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀* ṣe. 28 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà bọ̀ pẹ̀lú igbe ayọ̀+ àti pẹ̀lú ìró ìwo àti kàkàkí+ pẹ̀lú síńbálì, wọ́n sì ń fi àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ kọrin sókè.
-