-
1 Sámúẹ́lì 15:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Bí Sámúẹ́lì ṣe ń yíjú pa dà láti lọ, Sọ́ọ̀lù gbá etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ tí kò lápá mú, aṣọ náà bá fà ya. 28 Sámúẹ́lì wá sọ fún un pé: “Jèhófà ti fa ìṣàkóso Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ rẹ lónìí, yóò sì fún ọmọnìkejì rẹ tó sàn jù ọ́ lọ.+
-
-
1 Sámúẹ́lì 24:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ó sọ fún Dáfídì pé: “Òdodo rẹ ju tèmi lọ, torí o ti ṣe dáadáa sí mi, àmọ́ mo ti fi ibi san án fún ọ.+
-
-
1 Sámúẹ́lì 24:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Wò ó! Mo mọ̀ pé kò sí bí o kò ṣe ní di ọba tó máa ṣàkóso+ àti pé ìjọba Ísírẹ́lì máa pẹ́ lọ́wọ́ rẹ.
-