-
2 Sámúẹ́lì 21:8-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Nítorí náà, ọba mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rísípà+ ọmọ Áyà bí fún Sọ́ọ̀lù, ìyẹn, Árímónì àti Méfíbóṣétì, ó tún mú àwọn ọmọkùnrin márààrún tí Míkálì*+ ọmọ Sọ́ọ̀lù bí fún Ádíríélì+ ọmọ Básíláì ará Méhólà. 9 Ó fi wọ́n lé àwọn ará Gíbíónì lọ́wọ́, wọ́n sì gbé òkú wọn kọ́ sórí òkè níwájú Jèhófà.+ Àwọn méjèèje ló kú pa pọ̀, ọjọ́ àkọ́kọ́ ìkórè ni wọ́n pa wọ́n, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì. 10 Lẹ́yìn náà, Rísípà+ ọmọ Áyà mú aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì tẹ́ ẹ sórí àpáta, ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè títí òjò fi rọ̀ láti ọ̀run sórí àwọn òkú náà; kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn ní ọ̀sán tàbí kí àwọn ẹran inú igbó sún mọ́ wọn ní òru.
11 Wọ́n sọ fún Dáfídì nípa ohun tí Rísípà ọmọ Áyà ṣe, ìyẹn wáhàrì* Sọ́ọ̀lù.
-