-
Nọ́ńbà 16:46, 47Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
46 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Mú ìkóná, kí o fi iná sí i látorí pẹpẹ,+ kí o fi tùràrí sí i, kí o wá yára lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn,+ torí pé Jèhófà ti bínú sí wọn gan-an. Àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ̀rẹ̀!” 47 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì mú un, bí Mósè ṣe sọ, ó sì sáré lọ sáàárín ìjọ náà, wò ó! àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lù wọ́n. Ó wá fi tùràrí sí ìkóná náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ètùtù fún àwọn èèyàn náà.
-
-
Nọ́ńbà 25:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ló bá tẹ̀ lé ọkùnrin Ísírẹ́lì náà wọnú àgọ́, ó sì gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ, ó gún ọkùnrin Ísírẹ́lì náà àti obìnrin náà níbi ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀. Bí àjàkálẹ̀ àrùn tó kọ lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dáwọ́ dúró+ nìyẹn.
-