17 Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Dáfídì bàbá mi pé kí ó kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 18 Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Ìfẹ́ ọkàn rẹ ni pé kí o kọ́ ilé fún orúkọ mi, ó sì dára bó ṣe ń wù ọ́ yìí. 19 Àmọ́, ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé náà, ọmọ tí o máa bí ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+