-
2 Sámúẹ́lì 7:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nígbà tí ọba ti ń gbé inú ilé* rẹ̀,+ tí Jèhófà sì ti fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká, 2 ọba sọ fún wòlíì Nátánì+ pé: “Mò ń gbé inú ilé tí wọ́n fi igi kédárì kọ́+ nígbà tí Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wà láàárín àwọn aṣọ àgọ́.”+ 3 Nátánì dá ọba lóhùn pé: “Lọ ṣe ohunkóhun tó wà lọ́kàn rẹ, nítorí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”+
-