24 Torí náà, ó lé ọkùnrin náà jáde, ó sì fi àwọn kérúbù+ àti idà oníná tó ń yí láìdáwọ́ dúró sí ìlà oòrùn ọgbà Édẹ́nì, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ọ̀nà tó lọ síbi igi ìyè náà.
15 Hẹsikáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà+ níwájú Jèhófà, ó sọ pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí o jókòó sórí ìtẹ́ lókè* àwọn kérúbù,+ ìwọ nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ lórí gbogbo ìjọba ayé.+ Ìwọ lo dá ọ̀run àti ayé.