3Sólómọ́nì bá Fáráò ọba Íjíbítì dána. Ó fẹ́* ọmọbìnrin Fáráò,+ ó sì mú un wá sí Ìlú Dáfídì+ títí ó fi kọ́ ilé rẹ̀ parí+ àti ilé Jèhófà+ pẹ̀lú ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká.+
11 Bákan náà, Sólómọ́nì mú ọmọbìnrin Fáráò+ wá láti Ìlú Dáfídì sí ilé tó kọ́ fún un,+ torí ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó mi ni, kò yẹ kó máa gbé inú ilé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ibi tí Àpótí Jèhófà bá ti wọ̀ ti di mímọ́.”+