28 Ó sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Kò jẹun rárá, kò sì mu omi.+ Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sára àwọn wàláà náà, Òfin Mẹ́wàá.*+
9 Nígbà tí mo lọ sórí òkè láti gba àwọn wàláà òkúta,+ àwọn wàláà májẹ̀mú tí Jèhófà bá yín dá,+ ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru+ ni mo fi wà lórí òkè náà, tí mi ò jẹ, tí mi ò sì mu.