ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 18:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Kí ilẹ̀ náà má bàa pọ̀ yín jáde torí pé ẹ sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin, bó ṣe máa pọ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ṣáájú yín jáde.

  • Diutarónómì 4:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 mo fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí ta kò yín lónìí, pé ó dájú pé kíákíá lẹ máa pa run ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti lọ gbà. Ẹ ò ní pẹ́ níbẹ̀, ṣe lẹ máa pa run pátápátá.+

  • 2 Sámúẹ́lì 7:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi.+ Tí ó bá ṣe àìtọ́, màá fi ọ̀pá àti ẹgba àwọn ọmọ aráyé*+ bá a wí.

  • 2 Àwọn Ọba 17:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ń dá gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá.+ Wọn kò jáwọ́ nínú wọn 23 títí Jèhófà fi mú Ísírẹ́lì kúrò níwájú rẹ̀, bó ṣe sọ látẹnu gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.+ Bí wọ́n ṣe kó Ísírẹ́lì nígbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀ lọ sí Ásíríà+ nìyẹn, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.

  • Sáàmù 89:30-32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa òfin mi tì,

      Tí wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn àṣẹ* mi,

       31 Tí wọ́n bá rú òfin mi,

      Tí wọn ò sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́,

       32 Nígbà náà, màá fi ọ̀pá nà wọ́n nítorí àìgbọ́ràn* wọn,+

      Màá sì fi ẹgba nà wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́