38 Ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun. Ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta.+ 2 Ó wá ṣe àwọn ìwo sí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, ó fi bàbà bò ó.+