ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 11:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Jèróbóámù pé:

      “Gba mẹ́wàá yìí, torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómọ́nì, màá sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá.+

  • 1 Àwọn Ọba 12:32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Jèróbóámù tún dá àjọyọ̀ kan sílẹ̀ ní oṣù kẹjọ, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà, bí àjọyọ̀ tó wà ní Júdà.+ Ó rú ẹbọ sí àwọn ère ọmọ màlúù tó ṣe sórí àwọn pẹpẹ tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì yan àwọn àlùfáà ní Bẹ́tẹ́lì fún àwọn ibi gíga tó ṣe.

  • 1 Àwọn Ọba 14:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Nítorí ohun tí o ṣe yìí, màá mú àjálù bá ilé Jèróbóámù, màá pa gbogbo ọkùnrin* ilé Jèróbóámù rẹ́,* títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì, màá sì gbá ilé Jèróbóámù+ dà nù, bí ìgbà tí èèyàn gbá ìgbẹ́ ẹran kúrò láìku nǹkan kan!

  • 2 Kíróníkà 11:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ibi ìjẹko wọn àti ohun ìní wọn sílẹ̀,+ wọ́n wá sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, torí pé Jèróbóámù àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti lé wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà fún Jèhófà.+

  • 2 Kíróníkà 13:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Nítorí náà, Ábíjà kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lákíkanjú, tí wọ́n sì jẹ́ akọgun* lọ sójú ogun.+ Bákan náà, Jèróbóámù kó ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) àwọn ọkùnrin tó mọṣẹ́ ogun,* àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, ó sì tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti dojú kọ ọ́.

  • 2 Kíróníkà 13:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Jèróbóámù kò tún lágbára mọ́ nígbà ayé Ábíjà; níkẹyìn, Jèhófà kọ lù ú, ó sì kú.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́