-
2 Àwọn Ọba 23:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Nígbà tí Jòsáyà yíjú pa dà, tó sì rí àwọn sàréè tó wà lórí òkè, ó ní kí wọ́n kó àwọn egungun kúrò nínú àwọn sàréè náà, kí wọ́n sì sun wọ́n lórí pẹpẹ náà, kí ó lè sọ ọ́ di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ kéde, nígbà tó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀.+ 17 Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Èwo ni òkúta sàréè tí mò ń wò níbẹ̀ yẹn?” Àwọn èèyàn ìlú náà bá sọ fún un pé: “Sàréè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tó wá láti Júdà+ ni, ẹni tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí o ṣe sí pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì.”
-