-
2 Kíróníkà 16:11-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ní ti ìtàn Ásà, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.+
12 Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba Ásà, àrùn kan mú un ní ẹsẹ̀, ó sì di àìsàn ńlá sí i lára; síbẹ̀ nínú àìsàn tó wà, kò yíjú sí Jèhófà, àwọn oníṣègùn ló yíjú sí. 13 Níkẹyìn, Ásà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ ó kú ní ọdún kọkànlélógójì ìjọba rẹ̀. 14 Nítorí náà, wọ́n sin ín sí ibi ìsìnkú rẹ̀ tó lọ́lá, èyí tó gbẹ́ fún ara rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì;+ wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí àga ìgbókùú tí wọ́n ti fi òróró básámù sí lára àti oríṣiríṣi èròjà tí a pò mọ́ àkànṣe òróró ìpara.+ Síwájú sí i, wọ́n ṣe ìfinásun* tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí rẹ̀ nígbà ìsìnkú rẹ̀.
-